Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile
Folúkẹ́ Akínyẹmí

@fflakkyfoluke

Èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá|
Yorùbá Language Instructor| KíláàsìÈdèYorùbá via Zoom meeting| Thorn Carver¦¦ M°C|Broadcast journalist |Àwa Èwe¦Àyọkà ¦Jamz100.1fm

ID: 734622498

linkhttps://www.facebook.com/folukecommunications/ calendar_today03-08-2012 10:17:21

948 Tweet

2,2K Followers

1,1K Following

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Aṣọ Iyì Ìfẹ́ la fẹ́ ifá là fi fi ifá jọba lókè ọ̀dàn Ìfẹ́ la fẹ́ ọ̀pẹ̀lẹ̀ là fi fi ọ̀pẹ̀lẹ̀ jọba lókè ọ̀dàn Ǹjẹ́ Kínni ifá fi fẹ́tù? Gbogbo ara l'Ọ̀pẹ̀lẹ̀ fi fẹ́tù! Gbogbo ara. T'ọmọdé, T'àgbà; ẹ máa daṣọ Iyì bò mi Olùlànà kó lànà Ire kò mí Àṣẹ ire o

Aṣọ Iyì
Ìfẹ́ la fẹ́ ifá là fi fi ifá jọba lókè ọ̀dàn
Ìfẹ́ la fẹ́ ọ̀pẹ̀lẹ̀ là fi fi ọ̀pẹ̀lẹ̀ jọba lókè ọ̀dàn
Ǹjẹ́ Kínni ifá fi fẹ́tù?
Gbogbo ara l'Ọ̀pẹ̀lẹ̀ fi fẹ́tù! Gbogbo ara.
T'ọmọdé, T'àgbà; ẹ máa daṣọ Iyì bò mi
Olùlànà kó lànà Ire kò mí
Àṣẹ ire o
Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Ọdún Kérésìmesì Dé. Dear our Referrals, Parents, Adults and Young Yorùbá Language students. #kíláàsìèdèyorùbá I am saying thank you. Ẹ ṣeun gan-an ni ooo 🙏 Ojú wa yóò máa rí ọdún. Ire kà-ǹ-kà

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Oríkádún!!! Àtẹ̀pẹ́ ni àtẹ́lẹsẹ̀ mi yóò tẹ̀nà. Mo máa ṣe àṣeyọrí sí rere. Iwájú mi máa dára síi. Àṣẹ 🙏

Oríkádún!!! 
Àtẹ̀pẹ́ ni àtẹ́lẹsẹ̀ mi yóò tẹ̀nà.
Mo máa ṣe àṣeyọrí sí rere.
Iwájú mi máa dára síi.
Àṣẹ 🙏
Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

IRE GBOGBO Yin-ni-yin-ni kí ẹni le ṣe òmíì, A dífá fún Fátẹ́rù tíí ṣe ọmọkùnrin Ìgódó, Wọ́n ní ọ̀pẹ̀ à ń yìn ọ́, Olódùmarè kó o tún ṣe ohun ire míì si. Àṣẹ 🙏

IRE GBOGBO 
Yin-ni-yin-ni kí ẹni le ṣe òmíì, 
A dífá fún Fátẹ́rù tíí ṣe ọmọkùnrin Ìgódó, 
Wọ́n ní ọ̀pẹ̀ à ń yìn ọ́, 
Olódùmarè kó o tún ṣe ohun ire míì si.
Àṣẹ 🙏
Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Ọ̀rẹ́ mi 👂 : My Friend Ṣe Bí O Ti Mọ: 'Do your Bit' 'Bí a bá fi ẹyìn sí ọwọ́ ọ̀tún Tá a fi ẹyin sí ọwọ́ òsì Ká wá fi ẹ̀yìn rìn láti ìhà ìhín Títí dé Ìsẹ́yìn Ẹni máa yin ni Máa yin ni Ẹni kò ní yin ni Kò ní yin ni.' Listen to brymo 'ṣe bo ti mọ' Song.

Ọ̀rẹ́ mi 👂 : My Friend 
Ṣe Bí O Ti Mọ: 'Do your Bit'
'Bí a bá fi ẹyìn sí ọwọ́ ọ̀tún
Tá a fi ẹyin sí ọwọ́ òsì
Ká wá fi ẹ̀yìn rìn láti ìhà ìhín
Títí dé Ìsẹ́yìn
Ẹni máa yin ni
Máa yin ni
Ẹni kò ní yin ni
Kò ní yin ni.' 

Listen to <a href="/brymo/">brymo</a> 'ṣe bo ti mọ' Song.
Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Ìdí pìí Èrà pìí Obìnrin kú nílé ọkọ Ó lọ rèé jí nílé àlè Bó o kó ilá, o kó ilá Bó o gba ènì, o gba ènì Èwo làbùrọ̀ máa wojú olójà Lọ́jà Èjìgbò Aìwòó! Ojú òkú lò ń wò n nì (The story is from Odù Ògúndábèdé).

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Odù Ìrẹtẹ̀ Àdán: A já aagba nígbó Gbogbo ilẹ̀ Ìjẹ̀bú mì tì-tìi-tì A dá fún Kílo, A bù fún Àdán, Kílo p'Àdán s'ómi Àjàlóló; Kílo p'Àdán ó, S'ómi Àjàlóló' Kindly watch the full video here &subscribe too: youtu.be/ffZefSuegec?si…

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Odù Ìwòrì Ọ̀yẹ̀kú; Igbó etílé tòhun t'ẹ̀gbin Òwò àṣepọ̀ tòhun t'ìyà Ìwọ ò jù mí Èmi ò jù ọ́ Ni ará ilé ẹni Fií fojú di ni A dífá fún wọn ní Ìlúbìnrin Níbi Tí Egúngún wọn tí ń lé akọ kiri Ǹjẹ́ Ìwòrì ò r'ẹ̀kú Egúngún ò gbọ́dọ̀ na Babaláwo Ǹjẹ́ Ìwòrì ò r'ẹ̀kú

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Ọ̀bàrà Ọ̀wọ́nrín: Ìwàjọwà níí jẹ́ ọ̀rẹ́jọ̀rẹ́ Ọ̀bàrà Ọ̀wọ́nrín Ẹlẹ́fìrì A-mú-lẹ́nu ó j'abẹ lọ Òfò aàrè Ló dífá fún ajá Tíì ṣe ọmọ alábòró àkókó Ló dífá fún Olúgbẹ̀ẹ́-àdá Ọmọ bọ́kọrẹ́ òkú àgan Ló dífá fún òrí-òpómú Ọmọ akájalọ́dẹṣe

Folúkẹ́ Akínyẹmí (@fflakkyfoluke) 's Twitter Profile Photo

Odù Ogbè Ìrosùn :: Ọgbọ́n àgbọ́n-ọ̀n-gbọ̀n-tán Òró níí kọ́ ni Ààbọ̀ ìmọ̀ níí ta ara ẹ̀ lóṣì Ló dífá fún Ṣèyídá ọmọ Wọ̀nǹlè Tí yóò ki ara ẹ̀ mọ́ ẹbọ Òwe Yorùbá: Bí òní yìí ti rí, ọ̀la kìí rí bẹ́ẹ̀ ni kìí mú Babaláwo dífá ọrọọrún.